ORO IYAWO KO TII JE MI LOGUN BAYII – ADEKUNLE GOLD
Akorin ‘Sade’ ati ‘Dangote ko lori meji’, iyen Adekunle Gold, ti so pe oro iyawo ko tii je oun logun bayii.
O ni oro orin kiko lo wa lori emi oun.
Ohun ti a koko n gbo tele ni pe Adekunle Gold yoo se igbeyawo laipe yii, ati pe o seese pe Simi, ti oun naa n korin, lo fe fe.
Ninu iforowanilenuwo kan, Adekunle Gold ni 2014 ni oun fi ise ti oun n se tele sile lati kojumo orin kiko.
O ni nigba naa, awon eniyan kan ro pe ori oun ti daru ni, tori won gba pe o roju tan, o wa n wa airoju kiri.
Comments