2019: OBASANJO NI O TO GEE, KI BUHARI PADA SI DAURA
Aare Orile-ede yii tele, Oloye Olusegun Obasanjo, ti so fun Aare Muhammadu Buhari pe ko ma dabaa gbigbe apoti ibo ni 2019.
O ni ijoba re ti kuna ati pe ko si nnkan tuntun to tun fe se fun Naijiria mo.
Ninu leta nla kan ti Obasanjo ko si Buhari, o ni ireti awon eniyan lori ijoba Buhari ti ja si pabo.
O ni Buhari n se ojusaju lori bi o se n yan awon eniyan sipo ati bi o se n se lori ija buruku to n sele larin awon Fulani darandaran ati awon agbe.
Obasanjo tun so pe ko si eso rere Kankan ti APC ati PDP le so fun Naijria ni odun 2019.
O wa dabaa ki won gbe ajo kan dide ti yoo ri si bi Naijiria yoo se kuro ninuwahala to wa.
Comments