IBO GOMINA 2019: AJIMOBI WO ILE MI, SHITTU FI EJO GOMINA SUN AARE BUHARI




Bi ija fun 2019 yoo se ri ni Ipinle Oyo ti n foju han bayii.
Bi eniyan ba wo o lati okeere, yoo woye pe ija naa yoo wa laarin egbe APC ati PDP ni. Sugbon nigba ti a ko le so pe iro ni, o jo pe inu egbe APC gan-an ni roforofo naa yoo po si.
Ibeere akoko to n wa sokan opo eniyan ni pe, leyin ti Gomina Isiaka Ajimobi ba eewo eleekeji je, nipa wiwole leekan sii ni odun 2015, se yoo tun yege nipa ki eni to ba fowo si o bo si ipo leyin tie?

Bi awon alatako bii Ladoja ti gegun de e, bee naa ni oun naa n ta awon ayo kan. Lara eyi ni pe o ti fa Gomina tele, Adebayo Alao Akala, mora, bee, oloye egbe PDP Pataki miran tele, iyen …, naa ti darapo mo Ajimobi ni APC.
Sugbon ibi ti surutu wa bayii ni ti Minisita fun Oro Ibasoro ati Igbora Eni ye, Alhaji Adebayo Shitu, se n pee ati jade ni 2019.

Adebayo Shittu sun mo Aare Muhammadu Buhari ati awon oloye egbe APC ni Abuja. O si jo pe awon gan-an ni won n ti i leyin.
Lenu ojo meta yii, Shittu naa ti n se pe oun n gbe ija nla bo si Ibadan.
Lona kinni, o ti n wa ojuure Olubadan ti Ibadan, Oba Saliu Adetunji, nigba to ri i pe aarin Kabiyesi ati Ajimobi ko gun mo, latari bi ijoba re se gbe awon oba mokanlelogun dide lodun to lo.

Dukuu naa si wa nile, eyi to tun jeyo ni ilu Oyo lojo Sunday to lo, nigba ti Alaafin gbe opa ase le Aare Ona Kakanfo tuntun, Aare Gani Adams, lowo. Bi o tile je pe Ajimobi ati Olubadan jokoo sun mo ara won, won ko kira won dabi alara. Sugbon sa o, awon agbaagba Ibadan ti n sanna bi irepo yoo se wa laarin awon mejeeji.
Lose to lo bakan naa, Shitu fihan pe oun ni nnkan ninu nigba to soro odi si ijoba Ajimobi. Omo egbe APC ni awon mejeeji, to si je pe ko ye ki won maa ni etanu. Sugbon, ohun to n se ata ko se ora.

Ninu leta ibinu, iyen petition, ti Shittu ko si Aare Buhari, o ni Ajimobi n huwa buruku gege bii olori ijoba, asiwaju egbe ati omoniyan. O ni awon iwa to n hu ti fe so APC di eni eyin. O ni Ajimabi n soro asotan si awon eniyan. O ni Ajimobi tun wo ile ohun ni Saki, eyi to ti fe ki awon omo to n se Jambu ti maa jokoo se e, iyen CBT.O tun wa fi kun un pe Ajimobi n binu si oun latari bi Olubadan se fi oun joye Afiwajoye ti Ibadan. Boya loju ti gomina naa, ‘afotejoye’ lo ye ki won ma ape minisita naa ni.
Bakan naa, o se agbateru ifilole ipolongo ibo fun atiwole pada Aare Buhari ni 2019 ni ilu Ibadan, to si je pe Aimobi ko si nibe.

Ohun kan pataki to tun wa nidii oro yii ni pe afaimo ni ki oro Shittu ma tun hu aawo jade laarin Asiwaju Bola Tinubu ati awon to yi Buhari po ni Abuja – eyi ti awon kan n pe ni cabal.
Awon a fe ki Shittu gbe apoti gomina labe asia egbe APC ni 2019. Sugbon Ajimobi ko fe fi ara mo eyi. Bee, ti Ajimobi ni Tinubu n se!
Ohun to le tun je ki surutu naa le nip e Oke Ogun ni Shittu ti wa, bee awon ko tii je gomina Oyo ri. Bakan naa, awon olori egbe APC ni won yoo se agbateru idibo alabele egbe – iyen governorship primary, ki idibo 2019 to de. Bee, a mo ibi ti awon Oyegun fi si, ti Abuja ni won n se. Ti a ko ba gbagbe, awon naa ni won se eto idibo alabele ti Rotimi Akeredolu, nibi ti oludije ti Tinubu fara mo ti jakule.

Gbogbo bi eleyii se n lo lowo naa ni ile ejo ti gbegi le bi Ajimobi se gbe awon oba mokanlelogun miiran dide ni Ibadan ati agbegbe re. Ladoja lo gbe keesi naa lo sile ejo.
A ko tii mo ohun ti yoo sele leyin eleyii. Se ijoba fe pe ejo kotemilorun ni, abi won yoo ko awon ade igbalode naa pada lo si ibi ti won ti ko won wa.
… Ajimobi pe ejo kotemilorun lori awon oba
Ijoba Ipinle Oyo pe oun ejo kotemilorun lori bi ile ajo se so pe Gomina Isiaka Ajimobi ko lase lati gbe awon oba miiran dide.
Eyi tumo si pe kannakanna p’omo ega ni oro naa, ija n bo, ija koi de.
Se Yooba bo won ni ibere ogun laa ri, ote kan ko lomo rere ti i bi ju ete, abuku,ifaseyin, ohun idaru dapo lo.

Be e, bi rukerudo ba n fojoojumo suyo ninu ilu kan,ojuse awon agbaagba ibe ni lati ri i pe won lo gbogbo n Teledua fun won,lati lu ina ote naa pa fin in fin in.
Gbogbo awujo ti enu awon agbaagba ilu ko ba ti ko,ti imo o won pin yele yele, awon odo ilu be e ko le e rowo hori ,debi i pe awon naa yoo depo agba saye e re.
O da bi eni pe gbogbo akitiyan awon agbaagba ilu kan,nileebadan,lati ri i pe ina ote ko ru tu u mo,lori oro atunto Oye loba loba nileebadan, ni ko so eso rere o. Oro naa ko yato si egbinrin ote, ti won n pakan,ti kan tun n ru. 

Bi ko ba ri be e,o jo be e,tori pe ile ejo giga kan nileebadan kootu kewaa ti o kale so agbegbe Ring road ti gbe idajo o re kale bayi i pe,igbese Gomina Abiola Ajimobi lori abajade awon omo igbimo ti Adajo Akintunde Boade lewaju re lodi si ofin. Adajo Olajumoke Aiki gbe idajo re kale pe awon Oba mokanlelogun ti Gomina Abiola Ajimobi fi soroye ni gbagede Mapo ninuubadan ni ojo ketadinlogbon osu kejo odun 2017 ko ye loye ati pe agbeyewo atunto lori oro oye naa koja agbara gomina.

Adajo Olajumoke Aiki fi abala (section 10,12,25) kewaa, ikejila ati ikeedogbon ofin atunto oye lleebadan gbe oro o re lese pe oro atunto oye jije nileebadan koja a oju ti won fi wo o,ati pe won ko le samulo abala kan (section 25) lai wo abala yooku fini fini.
Ni bayii,oniruuru oro lo ti n lo lori idajo naa.Gomina papa a fohun akin pe igbese awon lori dide ade fawon oba tuntun naa kii se lati tabuku enikeni,bi ko se lati mu olaju ati idagbasoke to gbongbon ba ilu. 

Gomina Abiola Ajimobi ni ljoba oun ko nii kawo bo itan lori oro naa, awon yoo pe ejo tako agbekale idajo naa. Ni ifesi ti e, Agbaoye Rasid Adewolu Ladoja ,eni ti o ti je Gomina nigba kan ri nikan,ko jale nigba naa pe la,ese ofin lawon yoo fi yanju e,ti fesi si agbekale idajo naa pe ,o je aseyori nla gba a fun gbogbo omobibi iluubadan ati ipo Olubadan funraare. O ni agba kii wa loja kori omo tuntun wo,igbese ki igbese ti eda ba gbe loke eepe yii,itan lo n ko ,funraare,ati awon iran ti o n bo.

Hun! Bi egbinrin ote ba n lo bayii laarin yooba so yooba, nigbawo nidagbasoke ati ifokanbale fe ba ilu? Nigba wo la fe fenuko gba eto o wa nibi ti o ha si? Ogun abele tiran Yooba n ko jaraawon yii gan an lokunfa ijakule idagbasoke yooba. O dowo eyin agbaagba to mo riri irepo,ti isokan yooba so je logun. E gbiyanju pana ote ogun kii bimo o re. A ki i ti kootu bo ka tun sore e mule.

Comments

PIONEER PUNDIT

OLUBADAN CHIEFTAINCY: I AM DISAPPOINTED AT JUDGMENT, SAYS OBA LEKAN BALOGUN

BARR. SHITTU'S FACTION LEAVES OYO APC

KWAM 1 SPEAKS ON DAUGHTER'S DEATH

POPULAR JOURNALIST, ORIYOMI HAMZAT, FREED FROM SSS COUSTODY

OYO GUBER 2019: POST CRISIS AS LADOJA, ADESEUN, OTHERS PLAN TO LEAVE PDP

ACTRESS MOTUNRAYO ADEOYE IS DEAD

OLUBADAN: MOGAJIS ISSUE SEVEN-DAY ULTIMATUM TO 21 IBADAN KINGS