ÌJỌBA TÍ KÒ SÍ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ỌBA NI KÒ JẸ́ KÍ AYÉ Ó GÚN RÉGÉ MỌ́ – OLUWO
Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdul-Rasheed Adewale ni ohun ti ko je ki aye roju mo ko jina lati wa kiri. O ni ijoba ti ko si lowo awon Oba mo lo faa. O ni Oba nikan lo n ba Eledumare je oruko po ti awon wa je eni to wa laarin awon ara ilu ati Eledua. O ni awon ni Eledua fi gbogbo akoso ile aye le lowo, nitori pe Oba ni oko oso, oko aje ati oko elebo-loogun. Ti eku ko ba ke bi eku mo, ti eye ko ke bi eye mo tabi omo eniyan ti ko fohun bi omo eniyan. Oba nikan lo mo ohun ti a n se. Oba nikan lo mo bi a se n be awon alale ti gbogbo nnkan si maa bere si ni tuba-tuse. Oluwo pe akiyesi si asiko ti o je pe Oba lo n dari gbogbo nnkan ni ilu, o ni eyi to ba fe ru won loju, won mo bi won se n fi ese ile too, sugbon ti ko ri bee mo ni aye ode oni. Oluwo ni peluu bi o se ri yii naa, a ko gbodo kawo gbera, a ni lati kun won lowo naa ni nitori pe “Aafaa to ni iyan yoo mu, omo tire naa ko ni je tira”.