PAGA! ODO GBE AGUNBANIRO MEJI LO!
Ibanuje tun ti sele ni ile awon agunbaniro meji kan, ti oruko won n je Oguntola Wasiu Babatunde ati Danjuma Salihu, tori odo ti gbe awon mejeeji lo.
Ni ileto kan ti won n pe ni Assakio ni Lafia, ni Ipinle Nasarawa, ni isele laabi naa gbe se.
Asosu ajo NYSC ni agbegbe naa, Hajiya Zainab Isah, so pe ojo Sunday ti awon odomokunrin naa lo we lodo ni odo gbe won lo.
O ni, “Nnkan buruku ni isele naa, sugbon mo gbagbo pe Olorun yoo te won safefe rere.”
O wa wa ro awon agunbaniro to ku ki won maa sora se ni gbogbo ibi ti won ba wa.
Comments