IDI TI MO FI SO OMO MI NI FEMI ADEBAYO – OGA BELLO
Osere pataki, Alagba Adebayo Salami, ti so asiri bi o se so omo bibi inu re ti oun naa je elere fiimu, Femi Adebayo, ni oruko to n je di oni olonii.
O so ninu iforowanilenuwo kan pe oun so o ni Femi lati fi se ayesi fun baba-nigbejo oun kan ni, ti eni naa je Alagba Femi Okunnu.
Loya pataki ni baba naa je ni Eko, to si ti se opo ejo nla-nla ni aseyori.
Oga Bello ni ise loya lo wu oun lati se tele. O ni aisi owo ni ko je ki oun lo kawe gboye lori re.
O ni oun sise gege bii akowe ni oofisi Alagba Femi Okunnu nigba kan, ti baba naa si je baba-igbejo, iyen godfather fun oun di oni olonii.
Oga Bello wa salaye pe nigba ti oun bi Femi, ti oun fe so o loruko, oun wa pinnu pe oruko ti baba-nigbejo oun n je naa ni oun yoo fun un.
Oga Bello ni ninu gbogbo fiimu ti oun ti se, ASEWO TO RE MEECCA lo gbayi ju, to fun oun lowo ju, to si tubo so oun di ilumo-o-kaa.
Comments