EDE AIYEDE MAA N WAYE LAARIN EMI ATI IYAWO MI – MIKE BAMILOYE
Gbajugbaja oni fiimu ti emi, Mike Bamiloye, ti se alaye pe ede aiyede maa n waye laarin oun ati aya re, Gloria Bamidele leekokan.
Bi awon mejeeji se jo maa n se, paapaa niu fiimu, opo eniyan lo ro pe won kii jaa leekookan ni.
Sugbon nigba ti Mike Bamiloye n soro lori bi won se jo wa po fun odun mokandinlogbon gege bi loko-laya, o ni awon dupe lowo Olorun pe o fi oyin ati adun si igbeyawo awon, pelu awon omo to yan to yanju.
O ni aya rere ni Olorun fun oun, ti iyaafin naa, Gloria Bamiloye si so pe igbeyawo awon larinrin gidi ni.
Sugbon Mike Bamiloye ni leekookan, ede aiyede maa n wa ninu ile ati nigba ti awon ba n seto fiimu.
O ni bi eyi ba sewon a pe ara awon, awon a si soro nipa re, ti yoo si tan lokan kaluku awon.
Comments