GBENGA DANIEL FE BA BODE GEORGE FORI GBARI LORI ALAGA PDP
Bi egbe PDP se fe mu alaga re tutntun lati ile Yoruba ti fa ki awon olori egbe naa ni Kootu Oojiire maa da ofun tolo lori ipo naa o.
Awon akoni to n du ipo naa ti fee to meje, gege bi awon akoni Fagunwa ninu Igbo Irunmole.
Lara won to koko dide lati du ipo naa ni Oloye Bode George.
Bakan naa ni Alagba Jimi Agbaje, Ojogbon Tunde Adenuran ati Alhaji Taoheed Adedoja.
Sugbon lowolowo yii, Otunba Gbenga Daniel lo jo pe o n mile titi, to si ti n kaakiri Naijiria lati baa won agbaagba egbe dunaa-dura.
Comments