OMO WASIU AYINDE PARIWO SITA: ‘OLOLUFE MI FE KI N MAA LO OOGUN OLORO!’
Okan lara awon omo agba onifuji, Wasiu Ayinde, K1 De Ultimate, iyen Farouk Wasiu Ayinde, ti so asiri bi ololufe re kan se fe ti oun si ki oun maa lo oogun oloro bii cocaine, heroine ati awon miiran to gbona janjan.
Farouk, ti oun naa je akorin, so pe obinrin naa n so lemolemo pe oun naa gbodo maa ta si oogun oloro, bee oun ko setan lati se bee.
O ni ko si ni erongba oun lati maa ta si awon oogun buruku naa.
Comments