IDI TI MO FI N SE BUSINESS ADMINISTRATION NI UNILAG – ODUNLADE ADEKOLA
Laipe yii ni awon ololufe osere fiimu pataki, iyen Odunlade Adekola, yoo ba a je iresi, nigba ti o ba fe se ayeye ikekoo-jade ni University of Lagos.
Eko Business Administration, ti awon omo ile iwe maa n pe ni Bus Admin, ni o n se nibe, to si je pe odun karun-un , 500 Level lo wa.
O so fun awon oniroyin pe oun ti ni Diploma tele ni Moshood Abiola Polytechnic ni Abeokuta.
O ni idi ti oun fi yan Business Admin laayo ni pe o je ilana eko kan too wulo fun gbogbo eniyan. O ni bi eniyan lowo, o gbodo mo ona lati de e mole; bi eniyan nile ise, o gbodo ni imo Business Admin, to fi mo dokita to wa ni osibitu.
Comments