WON FI AMBULANSI GBE OLISA METUH LO SI KOOTU
Nnkan nla sele ni ilu Abuja ni ana, nigba ti won fi ambulansi gbe Agbenusu fun Egbe PDP tele, Oloye Olisa Metuh lo si kootu.
O jo pe ori aare nla ni o wa tori ori beedi alaare naa ni won gbe si, ti won si gbe e dilodilo lo si iwaju Adajo Abang Okon.
Loya Metuh ti so fun ile ejo tele pe ara onibara oun ko ya. Sugbon adajo ni dandan, o gbodo yoju si ile ejo, bi bee ko, oun a gbese le beeli re.
Boya adajo ro pe o n se mogomogo ni.
Sugbon nigba ti adajo ri Metuh ti won di bandeeji mo o lorun, ti won n gbe e dilodilo, o ni ki won yara gbe e pada si osibitu.
Inu osu keta lo fi igbejo si.
Metuh n jejo o iwa ibaje, lori esun pe o gba irinwo milionu naira lowo (N400m) lara owo to ye ki ijoba Goodluck Jonathan fi ra ohun ija ogun lati koju Boko Haram.
Comments