AARE MUHAMMED BUHARI GBE AWUYEWUYE EGBE APC KO ASIWAJU TINUBU LORUN
Orisiirisii isoro lo ti n jeyo ninu egbe oselu APC. Won n ja awon ija miran sita, awon kan je ikunsinu lasan. Bi wahala yii se wa ni ile Hausa ni awon ipinle bii Kaduna, Kano ati awon agbegbe miran, bee naa lo wa ni ile Yoruba.
Awon kan tile ti n gbee kiri pe gomina ana ni ipinle Eko, iyen Babatunde Raji Fashola, Ibikunle Amosu ti ipinle Ogun nitori Seneto Yayi to fe jade du ipo gomina ipinle Ogun maa ya lo si egbe miran.
Won ni bee lo wa laarin Abiola Ajimobi ti ipinle Oyo nitori minisita fun eto ibanisoro, Adebayo Situ to fe dije du ipo gomina ni odun to n bo ati bee bee lo.
Gbogbo isoro yii ni won ni o mu ki Aare Mohammadu Buhari woo pe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nikan lo le da egbe naa pada si bo se wa tele tabi ki o tun dara ju ti tele lo.
Iwonba osu perente ni Aare fun Asiwaju lati se atunse naa ki o to di pe ipolongo ibo wora.
Comments